Esekiẹli 11:9
Ezekiel 11:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí.
Ezekiel 11:9 in English
Ezekiel 11:9 · Berean Standard Bible
I will bring you out of the city and deliver you into the hands of foreigners, and I will execute judgments against you.
Context
7“Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀. 8Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa. 11Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.