Native Bible

Ezekiel 11:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”

Ezekiel 11:12 in English

Ezekiel 11:12 · Berean Standard Bible

Then you will know that I am the LORD. For you have neither followed My statutes nor practiced My ordinances, but you have conformed to the ordinances of the nations around you.”

Context

10Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa. 11Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. 12Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.” 13Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?” 14Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.