Esekiẹli 1:26
Ezekiel 1:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà.
Ezekiel 1:26 in English
Ezekiel 1:26 · Berean Standard Bible
Above the expanse over their heads was the likeness of a throne with the appearance of sapphire, and on the throne high above was a figure like that of a man.
Context
24Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀. 25Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. 26Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. 28Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká.
Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.