Esekiẹli 1:25
Ezekiel 1:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n.
Ezekiel 1:25 in English
Ezekiel 1:25 · Berean Standard Bible
And there came a voice from above the expanse over their heads as they stood still with their wings lowered.
Context
23Ìyẹ́ wọn sì tọ́ lábẹ́ òfúrufú, èkínní sí èkejì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tí ó bo ara wọn. 24Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀. 25Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. 26Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.