Native Bible

Ezekiel 1:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká.

Ezekiel 1:27 in English

Ezekiel 1:27 · Berean Standard Bible

From what seemed to be His waist up, I saw a gleam like amber, with what looked like fire within it all around. And from what seemed to be His waist down, I saw what looked like fire; and brilliant light surrounded Him.

Context

25Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. 26Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. 28Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká. Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.