Native Bible

Exodus 9:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

Exodus 9:15 in English

Exodus 9:15 · Berean Standard Bible

For by this time I could have stretched out My hand and struck you and your people with a plague to wipe you off the earth.

Context

13Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí, 14nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé. 15Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀. 16Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé. 17Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.