Native Bible

Exodus 9:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí,

Exodus 9:13 in English

Exodus 9:13 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to Moses, “Get up early in the morning, stand before Pharaoh, and tell him that this is what the LORD, the God of the Hebrews, says: ‘Let My people go, so that they may worship Me.

Context

11Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti. 12Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose. 13Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí, 14nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé. 15Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.