Eksodu 9:17
Exodus 9:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.
Exodus 9:17 in English
Exodus 9:17 · Berean Standard Bible
Still, you lord it over My people and do not allow them to go.
Context
15Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀. 16Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé. 17Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ. 18Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí. 19Pàṣẹ nísinsin yìí láti kó ẹran ọ̀sìn yín àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.