Native Bible

Exodus 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.

Exodus 9:16 in English

Exodus 9:16 · Berean Standard Bible

But I have raised you up * for this very purpose, that I might display My power to you,* and that My name might be proclaimed in all the earth.*

Context

14nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé. 15Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀. 16Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé. 17Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ. 18Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.