Native Bible

Exodus 30:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

Exodus 30:33 in English

Exodus 30:33 · Berean Standard Bible

Anyone who mixes perfume like it or puts it on an outsider shall be cut off from his people.’”

Context

31Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀. 32Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. 33Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ” 34Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òsùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ, 35ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.