Native Bible

Exodus 30:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́.

Exodus 30:35 in English

Exodus 30:35 · Berean Standard Bible

and make a fragrant blend of incense, the work of a perfumer, seasoned with salt, pure and holy.

Context

33Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ” 34Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òsùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ, 35ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́. 36Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín. 37Ẹ má ṣe ṣe tùràrí kankan ní irú èyí fúnra yín; ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.