Eksodu 30:36
Exodus 30:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín.
Exodus 30:36 in English
Exodus 30:36 · Berean Standard Bible
Grind some of it into fine powder and place it in front of the Testimony * in the Tent of Meeting, where I will meet with you. It shall be most holy to you.
Context
34Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òsùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ, 35ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́. 36Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín. 37Ẹ má ṣe ṣe tùràrí kankan ní irú èyí fúnra yín; ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa. 38Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.