Eksodu 30:31
Exodus 30:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀.
Exodus 30:31 in English
Exodus 30:31 · Berean Standard Bible
And you are to tell the Israelites, ‘This will be My sacred anointing oil for the generations to come.
Context
29Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́. 30“Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà. 31Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀. 32Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. 33Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.