Eksodu 15:16
Exodus 15:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta, títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa, títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.
Exodus 15:16 in English
Exodus 15:16 · Berean Standard Bible
and terror and dread will fall on them. By the power of Your arm they will be as still as a stone until Your people pass by, O LORD, until the people You have bought pass by.
Context
14Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì.
Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia. 15Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu,
àwọn olórí Moabu yóò wárìrì.
Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù. 16Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí
nína títóbi apá rẹ̀
wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta,
títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa,
títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá. 17Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n
ni orí òkè ti ìwọ jogún,
ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.
Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa. 18“Olúwa yóò jẹ ọba
láé àti láéláé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.