Native Bible

Exodus 15:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni orí òkè ti ìwọ jogún, ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa.

Exodus 15:17 in English

Exodus 15:17 · Berean Standard Bible

You will bring them in and plant them on the mountain of Your inheritance— the place, O LORD, You have prepared for Your dwelling, the sanctuary, O Lord, Your hands have established.

Context

15Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, àwọn olórí Moabu yóò wárìrì. Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù. 16Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta, títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa, títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá. 17Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni orí òkè ti ìwọ jogún, ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa. 18“Olúwa yóò jẹ ọba láé àti láéláé.” 19Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.