Eksodu 10:17
Exodus 10:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
Exodus 10:17 in English
Exodus 10:17 · Berean Standard Bible
Now please forgive my sin once more and appeal to the LORD your God, that He may remove this death from me.”
Context
15Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 16Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú. 17Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” 18Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 19Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.