Eksodu 10:15
Exodus 10:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.
Exodus 10:15 in English
Exodus 10:15 · Berean Standard Bible
They covered the face of all the land until it was black, and they consumed all the plants on the ground and all the fruit on the trees that the hail had left behind. Nothing green was left on any tree or plant in all the land of Egypt.
Context
13Nígbà náà ni Mose na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Ejibiti, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú wá; 14wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu eṣú bẹ́ẹ̀ rí, kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí. 15Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 16Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú. 17Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.