Native Bible

Exodus 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú.

Exodus 10:16 in English

Exodus 10:16 · Berean Standard Bible

Pharaoh quickly summoned Moses and Aaron and said, “I have sinned against the LORD your God and against you.

Context

14wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu eṣú bẹ́ẹ̀ rí, kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí. 15Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 16Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú. 17Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” 18Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.