Eksodu 10:19
Exodus 10:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
Exodus 10:19 in English
Exodus 10:19 · Berean Standard Bible
And the LORD changed the wind to a very strong west wind that carried off the locusts and blew them into the Red Sea.* Not a single locust remained anywhere in Egypt.
Context
17Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” 18Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 19Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti. 20Síbẹ̀ Olúwa ṣe àyà Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. 21Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí òkùnkùn bá à le bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti; àní òkùnkùn biribiri.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.