Native Bible

Exodus 10:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀ Olúwa ṣe àyà Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.

Exodus 10:20 in English

Exodus 10:20 · Berean Standard Bible

But the LORD hardened * Pharaoh’s heart, and he would not let the Israelites go.

Context

18Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 19Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti. 20Síbẹ̀ Olúwa ṣe àyà Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. 21Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí òkùnkùn bá à le bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti; àní òkùnkùn biribiri.” 22Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti fún ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.