Native Bible

Ecclesiastes 8:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

Ecclesiastes 8:4 in English

Ecclesiastes 8:4 · Berean Standard Bible

For the king’s word is supreme, and who can say to him, “What are you doing?”

Context

2Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. 3Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. 4Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?” 5Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan, àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é. 6Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe, ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.