Oniwaasu 8:3
Ecclesiastes 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Ecclesiastes 8:3 in English
Ecclesiastes 8:3 · Berean Standard Bible
Do not hasten to leave his presence, and do not persist in a bad cause, for he will do whatever he pleases.
Context
1Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn?
Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?
Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán
ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀. 2Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. 3Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. 4Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?” 5Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,
àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.