Native Bible

Ecclesiastes 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.

Ecclesiastes 4:3 in English

Ecclesiastes 4:3 · Berean Standard Bible

But better than both is he who has not yet existed, who has not seen the evil that is done under the sun.

Context

1Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára, wọn kò sì ní olùtùnú kankan. 2Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó sàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láààyè lọ. 3Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn. 4Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́. 5Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.