Oniwaasu 4:2
Ecclesiastes 4:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó sàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láààyè lọ.
Ecclesiastes 4:2 in English
Ecclesiastes 4:2 · Berean Standard Bible
So I admired the dead, who had already died, above the living, who are still alive.
Context
1Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,
mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni,
wọn kò sì ní olùtùnú kankan,
agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,
wọn kò sì ní olùtùnú kankan. 2Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú
tí wọ́n sì ti lọ,
ó sàn fún wọn ju àwọn
tí wọ́n sì wà láààyè lọ. 3Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju
àwọn méjèèjì lọ:
ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú
tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn. 4Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.