Oniwaasu 2:15
Ecclesiastes 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé, “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?” Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé, “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”
Ecclesiastes 2:15 in English
Ecclesiastes 2:15 · Berean Standard Bible
So I said to myself, “The fate of the fool will also befall me. What then have I gained by being wise?” And I said to myself that this too is futile.
Context
13Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀
gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ. 14Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,
nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,
ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀
wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì. 15Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,
“Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú
kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”
Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,
“Asán ni eléyìí pẹ̀lú.” 16Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;
gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.
Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn. 17Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.