Oniwaasu 2:14
Ecclesiastes 2:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀, nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀ wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.
Ecclesiastes 2:14 in English
Ecclesiastes 2:14 · Berean Standard Bible
The wise man has eyes in his head, but the fool walks in darkness. Yet I also came to realize that one fate overcomes them both.
Context
12Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,
àti ìsínwín àti àìgbọ́n
kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe
ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ. 13Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀
gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ. 14Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,
nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,
ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀
wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì. 15Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,
“Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú
kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”
Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,
“Asán ni eléyìí pẹ̀lú.” 16Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;
gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.
Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.