Native Bible

Ecclesiastes 2:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

Ecclesiastes 2:17 in English

Ecclesiastes 2:17 · Berean Standard Bible

So I hated life, because the work that is done under the sun was grievous to me. For everything is futile and a pursuit of the wind.

Context

15Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé, “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?” Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé, “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.” 16Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́; gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀. Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn. 17Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. 18Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. 19Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.