Native Bible

Ecclesiastes 11:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.

Ecclesiastes 11:6 in English

Ecclesiastes 11:6 · Berean Standard Bible

Sow your seed in the morning, and do not rest your hands in the evening, for you do not know which will succeed, whether this or that, or if both will equally prosper.

Context

4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè. 5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. 6Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà. 7Ìmọ́lẹ̀ dùn; Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn. 8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀. Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.