Oniwaasu 11:7
Ecclesiastes 11:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìmọ́lẹ̀ dùn; Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.
Ecclesiastes 11:7 in English
Ecclesiastes 11:7 · Berean Standard Bible
Light is sweet, and it pleases the eyes to see the sun.
Context
5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́
tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run
ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. 6Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́,
nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere
bóyá èyí tàbí ìyẹn
tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà. 7Ìmọ́lẹ̀ dùn;
Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn. 8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún
tí ó le è lò láyé
ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn
nítorí wọn ó pọ̀.
Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni. 9Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe
kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.
Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ
àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí
ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni
Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.