Native Bible

Ecclesiastes 11:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

Ecclesiastes 11:5 in English

Ecclesiastes 11:5 · Berean Standard Bible

As you do not know the path of the wind, or how the bones are formed * in a mother’s womb, so you cannot understand the work of God, the Maker of all things.

Context

3Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí. Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá, níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí. 4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè. 5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. 6Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà. 7Ìmọ́lẹ̀ dùn; Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.