Native Bible

Ecclesiastes 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí. Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá, níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.

Ecclesiastes 11:3 in English

Ecclesiastes 11:3 · Berean Standard Bible

If the clouds are full, they will pour out rain upon the earth; whether a tree falls to the south or to the north, in the place where it falls, there it will lie.

Context

1Fún àkàrà rẹ sórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà. 2Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú, nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀. 3Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí. Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá, níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí. 4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè. 5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.