Native Bible

Ecclesiastes 11:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún àkàrà rẹ sórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà.

Ecclesiastes 11:1 in English

Ecclesiastes 11:1 · Berean Standard Bible

Cast your bread upon the waters, for after many days you will find it again.

Context

1Fún àkàrà rẹ sórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà. 2Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú, nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀. 3Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí. Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá, níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.