Oniwaasu 10:11
Ecclesiastes 10:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.
Ecclesiastes 10:11 in English
Ecclesiastes 10:11 · Berean Standard Bible
If the snake bites before it is charmed, there is no profit for the charmer.
Context
9Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn. 10Bí àáké bá kú
tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;
yóò nílò agbára púpọ̀
ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá. 11Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,
kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀. 12Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́
ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò parun. 13Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;
ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.