Native Bible

Ecclesiastes 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò parun.

Ecclesiastes 10:12 in English

Ecclesiastes 10:12 · Berean Standard Bible

The words of a wise man’s mouth are gracious, but the lips of a fool consume him.

Context

10Bí àáké bá kú tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n; yóò nílò agbára púpọ̀ ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá. 11Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀. 12Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò parun. 13Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀; ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú. 14Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀. Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.