Native Bible

Ecclesiastes 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn; ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.

Ecclesiastes 10:9 in English

Ecclesiastes 10:9 · Berean Standard Bible

The one who quarries stones may be injured by them, and he who splits logs endangers himself.

Context

7Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin, nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú. 8Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an. 9Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn; ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn. 10Bí àáké bá kú tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n; yóò nílò agbára púpọ̀ ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá. 11Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.