Deuteronomi 32:42
Deuteronomy 32:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀, nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran: ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn, láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”
Deuteronomy 32:42 in English
Deuteronomy 32:42 · Berean Standard Bible
I will make My arrows drunk with blood, while My sword devours flesh— the blood of the slain and captives, the heads of the enemy leaders.”
Context
40Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,
Èmi ti wà láààyè títí láé, 41nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi
àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,
Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi
Èmi ó sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi. 42Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:
ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,
láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.” 43Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;
yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀
yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀. 44Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.