Deuteronomi 32:40
Deuteronomy 32:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé, Èmi ti wà láààyè títí láé,
Deuteronomy 32:40 in English
Deuteronomy 32:40 · Berean Standard Bible
For I lift up My hand to heaven and declare: As surely as I live forever,
Context
38ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?
Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!
Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín! 39“Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!
Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.
Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.
Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,
kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi. 40Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,
Èmi ti wà láààyè títí láé, 41nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi
àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,
Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi
Èmi ó sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi. 42Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:
ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,
láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.