Deuteronomi 32:38
Deuteronomy 32:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn? Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n! Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!
Deuteronomy 32:38 in English
Deuteronomy 32:38 · Berean Standard Bible
which ate the fat of their sacrifices and drank the wine of their drink offerings? Let them rise up and help you; let them give you shelter!
Context
36Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀
yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀
nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán
tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ. 37Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,
àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn, 38ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?
Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!
Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín! 39“Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!
Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.
Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.
Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,
kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi. 40Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,
Èmi ti wà láààyè títí láé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.