Deuteronomi 32:44
Deuteronomy 32:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni.
Deuteronomy 32:44 in English
Deuteronomy 32:44 · Berean Standard Bible
Then Moses came with Joshua * son of Nun and recited all the words of this song in the hearing of the people.
Context
42Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:
ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,
láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.” 43Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;
yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀
yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀. 44Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni. 45Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli. 46Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.