Native Bible

Deuteronomy 32:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa, àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.

Deuteronomy 32:31 in English

Deuteronomy 32:31 · Berean Standard Bible

For their rock is not like our Rock, even our enemies concede.*

Context

29Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí! 30Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000), tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá, bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ? 31Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa, àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́. 32Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra. Èso àjàrà wọn kún fún oró, ìdì wọn korò. 33Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni, àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.