Native Bible

Deuteronomy 32:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000), tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá, bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

Deuteronomy 32:30 in English

Deuteronomy 32:30 · Berean Standard Bible

How could one man pursue a thousand, or two put ten thousand to flight, unless their Rock had sold them, unless the LORD had given them up?

Context

28Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn. 29Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí! 30Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000), tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá, bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ? 31Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa, àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́. 32Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra. Èso àjàrà wọn kún fún oró, ìdì wọn korò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.