Native Bible

Deuteronomy 28:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.

Deuteronomy 28:17 in English

Deuteronomy 28:17 · Berean Standard Bible

Your basket and kneading bowl will be cursed.

Context

15Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ. 16Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko. 17Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ. 18Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ. 19Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.