Native Bible

Deuteronomy 28:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.

Deuteronomy 28:16 in English

Deuteronomy 28:16 · Berean Standard Bible

You will be cursed in the city and cursed in the country.

Context

14Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n. 15Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ. 16Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko. 17Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ. 18Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.