Deuteronomi 25:12
Deuteronomy 25:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe ṣàánú fún un.
Deuteronomy 25:12 in English
Deuteronomy 25:12 · Berean Standard Bible
you are to cut off her hand. You must show her no pity.
Context
10A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.” 11Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú. 12Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe ṣàánú fún un. 13Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. 14Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.