Native Bible

Deuteronomy 25:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.”

Deuteronomy 25:10 in English

Deuteronomy 25:10 · Berean Standard Bible

And his family name in Israel will be called “The House of the Unsandaled.”

Context

8Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,” 9opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.” 10A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.” 11Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú. 12Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe ṣàánú fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.