Native Bible

Deuteronomy 25:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”

Deuteronomy 25:9 in English

Deuteronomy 25:9 · Berean Standard Bible

his brother’s widow shall go up to him in the presence of the elders, remove his sandal, spit in his face, and declare, “This is what is done to the man who will not maintain his brother’s line.”

Context

7Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.” 8Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,” 9opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.” 10A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.” 11Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.