Deuteronomi 25:7
Deuteronomy 25:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”
Deuteronomy 25:7 in English
Deuteronomy 25:7 · Berean Standard Bible
But if the man does not want to marry his brother’s widow, she is to go to the elders at the city gate and say, “My husband’s brother refuses to preserve his brother’s name in Israel. He is not willing to perform the duty of a brother-in-law for me.”
Context
5Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn bá sì kú, tí kò sí ní ọmọkùnrin, kí aya òkú má ṣe ní àlejò ará òde ní ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni kí ó wọlé tọ̀ ọ́, kí ó fi ṣe aya, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ fún un. 6Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má ba á parẹ́ ní Israẹli. 7Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.” 8Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,” 9opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.