Native Bible

Deuteronomy 25:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré.

Deuteronomy 25:14 in English

Deuteronomy 25:14 · Berean Standard Bible

You shall not have two differing measures in your house, one large and one small.

Context

12Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe ṣàánú fún un. 13Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. 14Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. 15O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. 16Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.