Native Bible

Daniel 7:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

Daniel 7:8 in English

Daniel 7:8 · Berean Standard Bible

While I was contemplating the horns, suddenly another horn, a little one, came up among them, and three of the first horns were uprooted before it. This horn had eyes like those of a man and a mouth that spoke words of arrogance.

Context

6“Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba. 7“Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. 8“Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 9“Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná. 10Odò iná ń sàn, ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá. Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un; ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀. Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.