Daniẹli 7:9
Daniel 7:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.
Daniel 7:9 in English
Daniel 7:9 · Berean Standard Bible
As I continued to watch, thrones were set in place, and the Ancient of Days took His seat. His clothing was white as snow, and the hair of His head was like pure wool. His throne was flaming with fire, and its wheels were all ablaze.
Context
7“Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. 8“Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 9“Bí mo ṣe ń wò,
“a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀,
ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.
Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú;
irun orí rẹ̀ funfun bí òwú,
ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná.
Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná. 10Odò iná ń sàn,
ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá.
Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un;
ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀.
Àwọn onídàájọ́ jókòó,
a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀. 11“Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.